John 11:54 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, Jesu kò rìn ní gbangba mọ́ láàrin àwọn Juu, ṣugbọn ó kúrò níbẹ̀, ó lọ sí ìlú kan lẹ́bàá aṣálẹ̀, tí ó ń jẹ́ Efuraimu. Níbẹ̀ ni ó ń gbé pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina Jesu kò rìn ni gbangba larin awọn Ju mọ́; ṣugbọn o ti ibẹ̀ lọ si igberiko kan ti o sunmọ aginjù, si ilu nla ti à npè ni Efraimu, nibẹ̀ li o si wà pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà Jésù kò rìn ní gbangba láàárin àwọn Júù mọ́; ṣùgbọ́n ó ti ibẹ̀ lọ sí ìgbéríko kan tí ó sún mọ́ ihà, sí ìlú ńlá kan tí a ń pè ní Éfúráímù, níbẹ̀ ni ó sì wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.