John 12:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn Farisi bá ń bá ara wọn sọ pé, “Ẹ jókòó lásán ni! Òfo ni gbogbo làálàá yín já sí! Ẹ kò rí i pé gbogbo eniyan ni wọ́n ti tẹ̀lé e tán!”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina awọn Farisi wi fun ara wọn pe, Ẹ kiyesi bi ẹ kò ti le bori li ohunkohun? ẹ wò bi gbogbo aiye ti nwọ́ tọ̀ ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà àwọn Farisí wí fún ara wọn pé, “Ẹ kíyèsi bí ẹ kò ti lè borí ní ohunkóhun? Ẹ wo bí gbogbo ayé ti ń wọ́ tọ̀ ọ́!”