John 12:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jesu bá tún sọ pé, “Ọkàn mí dàrú nisinsinyii. Kí ni ǹ bá wí? Ọkàn kan ń sọ pé kí n wí pé, ‘Baba, yọ mí kúrò ninu àkókò yìí.’ Ṣugbọn nítorí àkókò yìí gan-an ni mo ṣe wá sí ayé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nisisiyi li a npọ́n ọkàn mi loju; kili emi o si wi? Baba, gbà mi kuro ninu wakati yi: ṣugbọn nitori eyi ni mo ṣe wá si wakati yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ní ìsinsin yìí ni a ń pọ́n ọkàn mi lójú; kínni èmi ó sì wí? ‘Baba, gbà mí kúrò nínú wákàtí yìí’? Rárá, ṣùgbọ́n nítorí èyì ni mo ṣe wá sí wákàtí yìí.