John 12:34 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn eniyan bi í pé, “A gbọ́ ninu òfin pé Mesaya wà títí lae. Kí ni ìtumọ̀ ohun tí o sọ pé dandan ni kí á gbé Ọmọ-Eniyan sókè? Ta ni ń jẹ́ Ọmọ-Eniyan?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina awọn ijọ enia da a lohùn wipe, Awa gbọ́ ninu ofin pe, Kristi wà titi lailai: iwọ ha ṣe wipe, A kò le ṣaima gbé Ọmọ-enia soke? tani iṣe Ọmọ-enia yi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà àwọn ìjọ ènìyàn dá a lóhùn pé, “Àwa gbọ́ nínú òfin pé, Kírísítì wà títí láéláé: ìwọ ha ṣe wí pé, ‘A ó gbé ọmọ ènìyàn sókè? Ta ni ó ń jẹ́ ọmọ ènìyàn yìí’?”