John 16:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jesu mọ̀ pé wọ́n ń fẹ́ bi òun léèrè ọ̀rọ̀ yìí. Ó wá wí fún wọn pé, “Nítorí èyí ni ẹ ṣe ń bá ara yín jiyàn, nítorí mo sọ pé, ‘Laìpẹ́ ẹ kò ní rí mi mọ́,’ ati pé, ‘Lẹ́yìn náà, láìpẹ́ ẹ óo tún rí mi?’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jesu sá ti mọ̀ pe, nwọn nfẹ lati bi on lẽre, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin mbi ara nyin lẽre niti eyi ti mo wipe, Nigba diẹ, ẹnyin kì o si ri mi: ati nigba diẹ ẹ̀wẹ, ẹnyin o si ri mi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jésù sáà ti mọ̀ pé, wọ́n ń fẹ́ láti bi òun léèrè, ó sì wí fún wọn pé, ẹ̀yin ń bi ara yín léèrè ní ti èyí tí mo wí pé, nígbà díẹ̀, ẹ̀yin kì ó sì rí mi: àti nígbà díẹ̀ ẹ̀wẹ̀, ẹ̀yin ó sì rí mi?