John 16:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ó bá dé, yóo fi han aráyé pé wọ́n ti ṣìnà ninu èrò wọn nípa ẹ̀ṣẹ̀, ati nípa òdodo, ati nípa ìdájọ́ Ọlọrun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati on ba si de, yio fi òye yé araiye niti ẹ̀ṣẹ, ati niti ododo, ati niti idajọ:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí òun bá sì dé, yóò fi òye yé aráíyé níti ẹ̀ṣẹ̀, àti ní ti òdodo, àti níti ìdájọ́: