John 17:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Baba, mo fẹ́ kí àwọn tí o fi fún mi wà pẹlu mi níbi tí èmi gan-an bá wà, kí wọ́n lè máa wo ògo tí o ti fi fún mi, nítorí o ti fẹ́ràn mi kí á tó fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Baba, emi fẹ ki awọn ti iwọ fifun mi, ki o wà lọdọ mi, nibiti emi gbé wà; ki nwọn le mã wò ogo mi, ti iwọ ti fi fifun mi: nitori iwọ sá fẹràn mi ṣiwaju ipilẹṣẹ aiye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Baba, èmi fẹ́ kí àwọn tí ìwọ fi fún mi, kí ó wà lọ́dọ̀ mi, níbi tí èmi gbé wà; kí wọn lè máa wo ògo mi, tí ìwọ ti fi fún mi: nítorí ìwọ sáà fẹ́ràn mi ṣíwájú ìpìlẹ̀ṣẹ̀ ayé.