John 18:28 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà wọ́n mú Jesu kúrò níwájú Kayafa lọ sí ààfin. Ilẹ̀ ti mọ́ ní àkókò yìí. Àwọn fúnra wọn kò wọ inú ààfin, kí wọn má baà di aláìmọ́, kí wọn baà lè jẹ àsè Ìrékọjá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina nwọn fa Jesu lati ọdọ Kaiafa lọ si ibi gbọ̀ngan idajọ: o si jẹ kùtukùtu owurọ̀; awọn tikarawọn kò wọ̀ ini gbọ̀ngàn idajọ, ki nwọn ki o má ṣe di alaimọ́, ṣugbọn ki nwọn ki o le jẹ àse irekọja.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà, wọ́n fa Jésù láti ọ̀dọ̀ Káyáfà lọ sí ibi gbọ̀ngàn ìdájọ́: ó sì jẹ́ kùtùkùtù òwúrọ̀; àwọn tìkara wọn kò wọ inú gbọ̀ngàn ìdájọ́, kí wọn má ṣe di aláìmọ́, ṣùgbọ́n kí wọn lè jẹ àsè ìrékọjá.