John 18:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
(Kí ọ̀rọ̀ tí ó ti sọ lè ṣẹ tí ó wí pé, “Ọ̀kan kan kò ṣègbé ninu àwọn tí o ti fi fún mi.”)
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ọ̀rọ nì ki o le ṣẹ, eyi ti o wipe, Awọn ti iwọ fifun mi, emi kò sọ ọ̀kan nù ninu wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ọ̀rọ̀ nì kí ó lè ṣẹ, èyí tó wí pé, Àwọn tí ìwọ fi fún mi, èmi kò sọ ọ̀kan nù nínú wọn.”