John 19:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n kan Jesu mọ́ agbelebu tán, àwọn ọmọ-ogun pín àwọn aṣọ rẹ̀ sí ọ̀nà mẹrin, wọ́n mú un ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. Ó wá tún ku àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀. Àwọ̀tẹ́lẹ̀ yìí kò ní ojúùrán, híhun ni wọ́n hun ún láti òkè dé ilẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana li awọn ọmọ-ogun, nigbati nwọn kàn jesu mọ agbelebu tan, nwọn mu aṣọ rẹ̀, nwọn si pín wọn si ipa mẹrin, apakan fun ọmọ-ogun kọkan, ati àwọtẹlẹ rẹ̀: ṣugbọn àwọ̀tẹlẹ na kò li ojuran, nwọn hun u lati oke titi jalẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni àwọn ọmọ ogun, nígbà tí wọ́n kan Jésù mọ́ àgbélébùú tán, wọ́n mú aṣọ rẹ̀, wọ́n sì pín wọn sí ipa mẹ́rin, apákan fún ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan, àti ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀: ṣùgbọ́n ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ náà kò ní ojúrán, wọ́n hun ún láti òkè títí jáde.