John 19:38 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ wọnyi, Josẹfu ará Arimatia bẹ Pilatu pé kí ó jẹ́ kí òun gbé òkú Jesu lọ. Josẹfu yìí jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jesu tí ó fara pamọ́ nítorí ó bẹ̀rù àwọn Juu. Pilatu bá fún un ní àṣẹ láti gbé òkú Jesu. Ó bá lọ gbé e.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lẹhin nkan wọnyi ni Josefu ará Arimatea, ẹniti iṣe ọmọ-ẹhin Jesu, ṣugbọn ni ikọ̀kọ nitori ìbẹru awọn Ju, o bẹ̀ Pilatu ki on ki o le gbé okú Jesu kuro: Pilatu si fun u li aṣẹ. Nitorina li o wá, o si gbé okú Jesu lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ní Jóṣéfù ará Arimatíyà, ẹni tí ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jésù, ṣùgbọ́n ní ìkọ̀kọ̀, nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù, o bẹ Pílátù kí òun lè gbé òkú Jésù kúrò: Pílátù sì fún un ní àṣẹ. Nígbà náà ni ó wá, ó sì gbé òkú Jésù lọ.