John 2:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, nígbà tí a ti jí i dìde kúrò ninu òkú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ranti pé ó ti sọ èyí fún wọn, wọ́n wá gba Ìwé Mímọ́ gbọ́ ati ọ̀rọ̀ tí Jesu ti sọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina nigbati o jinde kuro ninu okú, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ranti pe, o ti sọ eyi fun wọn; nwọn si gbà iwe-mimọ́ gbọ́, ati ọ̀rọ ti Jesu ti sọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà nígbà tí ó jíǹde kúrò nínú òkú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ rántí pé, ó ti sọ èyí fún wọn; wọ́n sì gba ìwé Mímọ́, àti ọ̀rọ̀ tí Jésù ti sọ gbọ́.