John 2:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Jesu wà ní agbègbè Jerusalẹmu ní àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá, ọpọlọpọ eniyan gba orúkọ rẹ̀ gbọ́ nígbà tí wọ́n ṣe akiyesi àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ń ṣe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati o si wà ni Jerusalemu, ni ajọ irekọja, lakoko ajọ na, ọ̀pọ enia gbà orukọ rẹ̀ gbọ nigbati nwọn ri iṣẹ àmi rẹ̀ ti o ṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ó sì wà ní Jérúsálẹ́mù, ní àjọ-ìrékọjá, lákókò àjọ náà, ọ̀pọ̀ ènìyàn gba orúkọ rẹ̀ gbọ́ nígbà tí wọ́n rí iṣẹ́ àmì tí ó ṣe.