John 20:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Jesu bá sọ fún un pé, “Mú ọwọ́ kúrò lára mi, nítorí n kò ì tíì gòkè tọ Baba mi lọ. Ṣugbọn lọ sọ́dọ̀ àwọn arakunrin mi, kí o sọ fún wọn pé, ‘Mò ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba mi ati Baba yín, Ọlọrun mi ati Ọlọrun yín.’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jesu wi fun u pe, Máṣe fi ọwọ́ kàn mi; nitoriti emi kò ti igòke lọ sọdọ Baba mi: ṣugbọn lọ sọdọ awọn arakunrin mi, si wi fun wọn pe, Emi ngòke lọ sọdọ Baba mi, ati Baba nyin; ati sọdọ Ọlọrun mi, ati Ọlọrun nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jésù wí fún un pé, “Má ṣe fi ọwọ́ kàn mí; nítorí tí èmi kò tíì gókè lọ sọ́dọ̀ Baba mi: ṣùgbọ́n, lọ sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin mi, sì wí fún wọn pé, ‘Èmi ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba mi, àti Baba yín: àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run mi, àti Ọlọ́run yín.’ ”