John 20:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn a kọ ìwọ̀nyí kí ẹ lè gbàgbọ́ pé Jesu ni Mesaya, Ọmọ Ọlọrun, ati pé tí ẹ bá gbàgbọ́, kí ẹ lè ní ìyè ní orúkọ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn wọnyi li a kọ, ki ẹnyin ki o le gbagbọ́ pe, Jesu ni iṣe Kristi na, Ọmọ Ọlọrun; ati ni gbigbàgbọ́, ki ẹnyin ki o le ni ìye li orukọ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n wọ̀nyí ni a kọ, kí ẹ̀yin lè gbàgbọ́ pé Jésù ní í ṣe Kírísítì náà, Ọmọ Ọlọ́run, àti pé gbígbàgbọ́, kí ẹ̀yin lè ní ìyè ní orúkọ rẹ̀.