John 21:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà náà ni Simoni Peteru gòkè, ó fa àwọ̀n sí èbúté. Àwọ̀n náà kún fún ẹja ńláńlá, mẹtalelaadọjọ. Ṣugbọn bí wọ́n ti pọ̀ tó yìí, àwọ̀n náà kò ya.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina Simoni Peteru gòke, o si fà àwọn na wálẹ, o kún fun ẹja nla, o jẹ mẹtalelãdọjọ: bi nwọn si ti pọ̀ to nì, àwọn na kò ya.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà Símónì Pétérù gòkè, ó sì fa àwọ̀n náà wálẹ̀, ó kún fún ẹja ńlá, ó jẹ́ mẹ́taléláádọ́jọ: bí wọ́n sì ti pọ̀ tó náà, àwọ̀n náà kò ya.