John 21:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Peteru bojú wẹ̀yìn, ó rí ọmọ-ẹ̀yìn tí Jesu fẹ́ràn tí ó ń tẹ̀lé e. Òun ni ó súnmọ́ Jesu pẹ́kípẹ́kí nígbà tí wọn ń jẹun, tí ó bi Jesu pé, “Oluwa, ta ni yóo fi ọ́ lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ rí?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Peteru si yipada, o ri ọmọ-ẹhin nì, ẹniti Jesu fẹràn, mbọ̀ lẹhin; ẹniti o si rọ̀gun si àiya rẹ̀ nigba onjẹ alẹ ti o si wi fun u pe, Oluwa, tali ẹniti o fi ọ hàn?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Pétérù sì yípadà, ó rí ọmọ-ẹ̀yìn náà, ẹni tí Jésù fẹ́ràn, ń bọ̀ lẹ́yìn; ẹni tí ó fararọ̀ súnmọ́ àyà rẹ̀ nígbà oúnjẹ alẹ́ tí ó sì wí fún un pé, “Olúwa, ta ni ẹ̀ni tí ó fi ọ́ hàn?”