John 21:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọpọlọpọ nǹkan mìíràn ni Jesu ṣe, bí a bá kọ wọ́n ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, mo rò pé kò ní sí ààyè tó ní gbogbo ayé tí yóo gba ìwé tí a bá kọ wọ́n sí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọpọlọpọ ohun miran pẹlu ni Jesu ṣe, eyiti bi a ba kọwe wọn li ọkọ̃kan, mo rò pe aiye pãpã kò le gbà iwe na ti a ba kọ. Amin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun mìíràn pẹ̀lú ni Jésù ṣe, èyí tí bí a bá kọ̀wé wọn ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, mo rò pé gbogbo ayé pàápàá kò lè gba ìwé náà tí a bá kọ ọ́. Àmín