John 3:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Johanu náà ń ṣe ìrìbọmi fún àwọn eniyan ní Anoni lẹ́bàá Salẹmu, nítorí omi pọ̀ níbẹ̀. Àwọn eniyan ń wọ́ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì ń ṣe ìrìbọmi fún wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Johanu pẹlu si mbaptisi ni Ainoni, li àgbegbe Salimu, nitoriti omi pipọ wà nibẹ̀: nwọn si nwá, a si baptisi wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jòhánù pẹ̀lú sì ń ṣe ìtẹ̀bọmi ní Áhínónì, ní agbégbé Sálímù, nítorí tí omi púpọ̀ wà níbẹ̀: wọ́n sì ń wá, a sì ń tẹ̀ ẹ́ wọn bọmi.