John 3:29 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọkọ iyawo ni ó ni iyawo, ṣugbọn ẹni tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ ọkọ iyawo, tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀, tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, á máa láyọ̀ láti gbọ́ ohùn ọkọ iyawo. Nítorí náà ayọ̀ mi yìí di ayọ̀ kíkún.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹniti o ba ni iyawo ni ọkọ iyawo; ṣugbọn ọrẹ́ ọkọ iyawo ti o duro ti o si ngbohùn rẹ̀, o nyọ̀ gidigidi nitori ohùn ọkọ iyawo; nitorina ayọ̀ mi yi di kíkun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹni tí ó bá ni ìyàwó ni ọkọ ìyàwó; ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó tí ó dúró tí ó sì ń gbóhùn rẹ̀, ó ń yọ̀ gidigidi nítorí ohùn ọkọ ìyàwó; nítorí náà ayọ̀ mi yí di kíkún.