John 5:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí èyí àwọn Juu dìtẹ̀ sí Jesu, nítorí ó ń ṣe nǹkan wọnyi ní Ọjọ́ Ìsinmi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori eyi li awọn Ju si nṣe inunibini si Jesu, nwọn si nwá ọ̀na ati pa a, nitoriti a nṣe nkan wọnyi li ọjọ isimi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí èyí ni àwọn Júù ṣe inúnibíni sí Jésù, wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa á, nítorí tí Ó ń ṣe nǹkan wọ̀nyí ní ọjọ́ ìsinmi.