John 5:36 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn mo ní ẹ̀rí tí ó tóbi ju ti Johanu lọ. Àwọn iṣẹ́ tí Baba ti fún mi pé kí n parí, àní àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe, àwọn ni ẹlẹ́rìí mi pé Baba ni ó rán mi níṣẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn emi ni ẹri ti o pọ̀ju ti Johanu lọ: nitori iṣẹ ti Baba ti fifun mi lati ṣe pari, iṣẹ na pãpã ti emi nṣe ni njẹri mi pe, Baba li o rán mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ṣùgbọ́n èmi ní ẹ̀rí tí ó pọ̀ju ti Jòhánù lọ: nítorí iṣẹ́ tí Baba ti fi fún mi láti ṣe parí, iṣẹ́ náà pàápàá tí èmi ń ṣe náà ń jẹ́rí mi pé, Baba ni ó rán mi.