John 6:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jesu ní, “Ẹ ní kí wọ́n jókòó.” Koríko pọ̀ níbẹ̀. Àwọn eniyan náà bá jókòó. Wọ́n tó bí ẹgbẹẹdọgbọn (5,000).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jesu si wipe, Ẹ mu ki awọn enia na joko. Koriko pipọ si wà nibẹ̀. Bẹ̃li awọn ọkunrin na joko, ìwọn ẹgbẹdọgbọn enia ni iye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jésù sì wí pé, “Ẹ mú kí àwọn ènìyàn náà jókòó!” Kóríkó púpọ̀ sì wá níbẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin náà jókòó; ìwọ̀n ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn ní iye.