John 6:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Jesu gbé ojú sókè, ó rí ọ̀pọ̀ eniyan tí ó wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó wá bi Filipi pé, “Níbo ni a ti lè ra oúnjẹ fún àwọn eniyan yìí láti jẹ?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ bi Jesu ti gbé oju rẹ̀ soke, ti o si ri ọ̀pọ enia wá sọdọ rẹ̀, o wi fun Filippi pe, Nibo li a o ti rà akara, ki awọn wọnyi le jẹ?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ǹjẹ́ bí Jésù ti gbé ojú rẹ̀ sókè, tí ó sì rí ọ̀pọ̀ ènìyàn wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó wí fún Fílípì pé, “Níbo ni a ó ti ra àkàrà, kí àwọn wọ̀nyí lè jẹ?”