John 6:53 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jesu wá wí fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, bí ẹ̀yin kò bá jẹ ẹran ara ọmọ eniyan, kí ẹ sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ kò lè ní ìyè ninu yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Bikoṣepe ẹnyin ba jẹ ara Ọmo-enia, ki ẹnyin si mu ẹ̀jẹ rẹ̀, ẹnyin kò ni ìye ninu nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Jésù wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí kò ṣe pé ẹ̀yin bá jẹ ara ọmọ ènìyàn, kí ẹ sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ̀yin kò ní ìyè nínú yin.