John 7:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Oríṣìíríṣìí ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ ni àwọn eniyan ń sọ nípa rẹ̀. Àwọn kan ń sọ pé, “Eniyan rere ni.” Ṣugbọn àwọn mìíràn ń sọ pé, “Rárá o, ó ń tan àwọn eniyan jẹ ni.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kikùn pipọ si wà larin awọn ijọ enia nitori rẹ̀: nitori awọn kan wipe, Enia rere ni iṣe: awọn miran wipe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn o ntàn enia jẹ ni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kíkùn púpọ̀ sì wà láàárin àwọn ìjọ ènìyàn nítorí rẹ̀: nítorí àwọn kan wí pé, “Ènìyàn rere níí ṣe.” Àwọn mìíràn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n òun ń tan ènìyàn jẹ ni.”