John 7:32 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn Farisi gbọ́ pé àwọn eniyan ń sọ ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ báyìí láàrin ara wọn nípa Jesu. Àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi wá rán àwọn ẹ̀ṣọ́ Tẹmpili pé kí wọ́n lọ mú Jesu wá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn Farisi gbọ́ pe, ijọ enia nsọ nkan wọnyi labẹlẹ̀ nipa rẹ̀; awọn Farisi ati awọn olori alufã si rán awọn onṣẹ lọ lati mu u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn Farisí gbọ́ pé, ìjọ ènìyàn ń sọ nǹkan wọ̀nyí lábẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀; àwọn Farisí àti àwọn olórí àlùfáà sì rán àwọn onísẹ́ lọ láti mú un.