John 7:35 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn Juu bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Níbo ni ọkunrin yìí yóo lọ tí àwa kò fi ní rí i? Àbí ó ha fẹ́ lọ sí ààrin àwọn ará wa tí ó fọ́nká sí ààrin àwọn Giriki ni?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina li awọn Ju mba ara wọn sọ pe, Nibo ni ọkunrin yi yio gbé lọ, ti awa kì yio fi ri i? yio ha lọ sarin awọn Hellene ti nwọn fọnká kiri, ki o si ma kọ́ awọn Hellene bi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà ni àwọn Júù ń bá ara wọn sọ pé, “Níbo ni ọkùnrin yìí yóò gbé lọ tí àwa kì yóò fi rí i? Yóò ha lọ sí àárin àwọn Hélénì tí wọ́n fọ́n káàkiri, kí ó sì máa kọ́ àwọn Hélenì bí.