John 8:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lọ lọ́kọ̀ọ̀kan, àwọn àgbààgbà ni wọ́n kọ́ lọ. Gbogbo wọ́n bá túká pátá láìku ẹnìkan. Ó wá ku obinrin yìí nìkan níbi tí ó dúró sí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati nwọn gbọ eyi, nwọn si jade lọ lọkọ̃kan, bẹrẹ lati ọdọ awọn àgba titi de awọn ti o kẹhin; a si fi Jesu nikan silẹ, ati obinrin na lãrin, nibiti o ti wà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, (tí ẹ̀rí-ọkan wọn sì dá wọn lẹ́bi) wọ́n sì jáde lọ lọ́kọ̀ọ̀kan, bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn àgbà títí dé àwọn tí ó kẹ́yìn; a sì fi Jésù nìkan sílẹ̀, àti obìnrin náà láàárin, níbi tí ó wà.