John 9:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n bi wọ́n pé, “Ọmọ yín nìyí, tí ẹ sọ pé ẹ bí ní afọ́jú? Báwo ni ó ti ṣe wá ríran nisinsinyii?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si bi wọn lẽre, wipe, Eyi li ọmọ nyin, ẹniti ẹnyin wipe, a bí i li afọju? ẽhaṣe ti o riran nisisiyi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì bi wọ́n léèrè wí pé, “Ǹjẹ́ èyí ni ọmọ yín, ẹni tí ẹ̀yin wí pé, a bí ní afọ́jú? Báwo ni ó ṣe ríran nísinsin yìí?”