Jonah 1:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn Jona gbéra ó fẹ́ sálọ sí Taṣiṣi, kí ó lè kúrò níwájú OLUWA. Ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Jọpa, ó sì rí ọkọ̀ ojú omi kan tí ń lọ sí Taṣiṣi níbẹ̀. Ó san owó ọkọ̀, ó bá bọ́ sinu ọkọ̀, ó fẹ́ máa bá a lọ sí Taṣiṣi kí ó sì sá kúrò níwájú OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Jona dide lati sá lọ si Tarṣiṣi kuro niwaju Oluwa, o si sọkalẹ lọ si Joppa; o si ri ọkọ̀ kan ti nlọ si Tarṣiṣi: bẹ̃li o sanwo ọkọ, o si sọkalẹ sinu rẹ̀, lati ba wọn lọ si Tarṣiṣi lati sá kuro niwaju Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Jónà dìde kúrò láti sá lọ sí Tásísì kúrò níwájú OLÚWA, ó sì ṣọ̀kalẹ̀ lọ sí Jópà, ìbí ti ó tí rí ọkọ̀ kan tí ń lọ sí Tásísì: lẹ́yìn ti ó sanwó ọkọ̀, ó wọlé sínú rẹ̀, láti bá wọn lọ sí Tásísì kúrò níwájú OLÚWA.