Jonah 1:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ̀rù ba àwọn tí wọn ń tu ọkọ̀, olukuluku bá bẹ̀rẹ̀ sí ké pe oriṣa rẹ̀, wọ́n ń da ẹrù wọn tí ó wà ninu ọkọ̀ sinu òkun kí ọkọ̀ lè fúyẹ́. Ṣugbọn Jona ti lọ dùbúlẹ̀ sí ìsàlẹ̀ ọkọ̀, ó sì ti sùn lọ fọnfọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni awọn atukọ̀ bẹ̀ru, olukuluku si kigbe si ọlọrun rẹ̀, nwọn ko ẹrù ti o wà ninu ọkọ dà sinu okun, lati mu u fẹrẹ. Ṣugbọn Jona sọkalẹ lọ si ẹ̀gbẹ́ ọkọ̀; o si dubulẹ sùn wọra.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni àwọn atukọ̀ bẹ̀rù, olúkúlùkù sì ń kígbe sí ọlọ́run rẹ̀, wọ́n kó ẹrù tí ó wà nínú ọkọ̀ dà sínú òkun, kí ó bá à lè fúyẹ́. Ṣùgbọ́n Jónà sọ̀kalẹ̀ lọ sí ẹ̀gbẹ́ ọkọ̀ ó sì dùbúlẹ̀, ó sùn wọra.