Jonah 2:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo já sí ibi tí ó jìn jùlọ ninu òkun, àní ibi tí ẹnikẹ́ni kò lọ ní àlọ-bọ̀ rí. Ṣugbọn ìwọ, OLUWA Ọlọrun mi, o mú ẹ̀mí mi jáde láti inú ibú náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi sọkalẹ lọ si isalẹ awọn oke nla; ilẹ aiye pẹlu idenà rẹ̀ wà yi mi ka titi: ṣugbọn iwọ ti mu ẹmi mi wá soke lati inu ibú wá, Oluwa Ọlọrun mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi ṣọ̀kalẹ̀ lọ sí ìṣàlẹ̀ àwọn òkè ńlá; ilẹ̀ ayé pẹ̀lú ìdènà rẹ̀ yí mi ká títí: ṣùgbọ́n ìwọ ti mú ẹ̀mí mi wá sókè láti inú ibú wá, OLÚWA Ọlọ́run mi.