Jonah 3:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ará Ninefe gba ọ̀rọ̀ Ọlọrun gbọ́, wọ́n bá kéde pé kí gbogbo eniyan gbààwẹ̀, àtọmọdé, àtàgbà, wọ́n sì da aṣọ ọ̀fọ̀ bora.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn enia Ninefe si gba Ọlọrun gbọ́, nwọn si kede awẹ̀, nwọn si wọ aṣọ ọ̀fọ, lati agbà wọn titi de kekere wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ènìyàn Nínéfè sì gba Ọlọ́run gbọ́. Wọ́n sì kéde ààwẹ̀, gbogbo wọ́n sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, bẹ̀rẹ̀ lati orí ọmọdé títí dé orí àgbà wọn.