Jonah 3:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn kí gbogbo wọn fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora, kí wọ́n sì fi gbogbo ọkàn wọn gbadura sí Ọlọrun. Kí olukuluku pa ọ̀nà burúkú ati ìwà ipá tí ó wà lọ́wọ́ rẹ̀ tì.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn jẹ ki enia ati ẹranko fi aṣọ ọ̀fọ bora, ki nwọn si kigbe kikan si Ọlọrun: si jẹ ki nwọn yipada, olukuluku kuro li ọ̀na ibi rẹ̀, ati kuro ni ìwa agbara ti o wà lọwọ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ènìyàn àti ẹranko da aṣọ ọ̀fọ̀ bo ara, kí wọn sì kígbe kíkan sí Ọlọ́run, sì jẹ́ kí wọn yípadà, olúkúlùkù kúrò ní ọ̀nà ibi rẹ̀ àti kúrò ní ìwà ìpa tí ó wà lọ́wọ́ wọn.