Joshua 1:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn aya yín, àwọn ọmọ yín kéékèèké, ati àwọn ẹran ọ̀sìn yín ni yóo kù lẹ́yìn lórí ilẹ̀ tí Mose fun yín ní òdìkejì odò Jọdani; ṣugbọn gbogbo àwọn akọni láàrin yín yóo rékọjá sí òdìkejì odò náà pẹlu ihamọra ogun níwájú àwọn arakunrin yín, wọn yóo máa ràn wọ́n lọ́wọ́
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn obinrin nyin, ati awọn ọmọ wẹrẹ nyin, ati ohunọ̀sin nyin, yio joko ni ilẹ ti Mose fi fun nyin ni ìha ihin Jordani; ṣugbọn ẹnyin o gòke lọ niwaju awọn arakunrin nyin ni ihamọra, gbogbo awọn alagbara akọni, ẹnyin o si ràn wọn lọwọ,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ìyàwó yín, àwọn ọmọ yín àti àwọn ẹran ọ̀sìin yín lè dúró ní ilẹ̀ tí Móṣè fún un yin ní ìlà-oòrùn Jọ́dánì; ṣùgbọ́n gbogbo àwọn jagunjagun un yín, pẹ̀lú ìhámọ́ra ogun gbọdọ̀ kọjá ṣíwájú àwọn arákùnrin yín. Ẹ̀yin yóò sì rán àwọn arákùnrin yín lọ́wọ́