Joshua 10:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí wọ́n sì ti ń sá lọ fún àwọn ọmọ Israẹli, tí wọ́n sì ń sọ̀kalẹ̀ ní ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Beti Horoni, OLUWA mú kí àwọn òkúta ńláńlá máa bọ́ lù wọ́n láti ojú ọ̀run, títí tí wọ́n fi dé Aseka, wọ́n sì kú. Àwọn tí òkúta ńláńlá wọnyi pa pọ̀ ju àwọn tí àwọn ọmọ Israẹli fi idà pa lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, bi nwọn ti nsá niwaju Israeli, ti nwọn dé gẹrẹgẹrẹ Beti-horoni, OLUWA rọ̀ yinyin nla si wọn lati ọrun wá titi dé Aseka, nwọn si kú: awọn ti o ti ipa yinyin kú, o pọ̀ju awọn ti awọn ọmọ Israeli fi idà pa lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí wọ́n sì tí ń sá ní iwájú Ísírẹ́lì ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ní ọ̀nà láti Bẹti-Hórónì títí dé Ásékà, OLÚWA rọ yìnyín ńlá sí wọn láti ọ̀run wá, àwọn tí ó ti ipa yìnyín kú sì pọju àwọn tí àwọn ará Ísírẹ́lì fi idà pa lọ.