Joshua 10:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ọjọ́ tí OLUWA fi àwọn ará Amori lé àwọn ọmọ Israẹli lọ́wọ́, Joṣua bá OLUWA sọ̀rọ̀ lójú gbogbo Israẹli, ó ní, “Ìwọ oòrùn, dúró jẹ́ẹ́ ní Gibeoni. Ìwọ òṣùpá, sì dúró jẹ́ẹ́ ní àfonífojì Aijaloni.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Joṣua wi fun OLUWA li ọjọ́ ti OLUWA fi awọn Amori fun awọn ọmọ Israeli, o si wi li oju Israeli pe, Iwọ, Õrùn, duro jẹ lori Gibeoni; ati Iwọ, Oṣupa, li afonifoji Aijaloni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ̀ tí OLÚWA fi àwọn ọmọ Ámórì lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́, Jóṣúà sọ fún OLÚWA níwájú àwọn ará Ísírẹ́lì: “Ìwọ oòrùn, dúró jẹ́ẹ́ ní orí Gíbíónì, Ìwọ òṣùpá, dúró jẹ́ẹ́ lórí àfonífojì Áíjálónì.”