Joshua 10:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli ti pa wọ́n ní ìpakúpa tán, tí wọ́n sì fẹ́rẹ̀ pa gbogbo wọn run, tí àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù sì ti sá wọ àwọn ìlú olódi wọn lọ tán,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati Joṣua ati awọn ọmọ Israeli pa wọn ni ipakupa tán, titi a fi run wọn, ti awọn ti o kù ninu wọn wọ̀ inu ilu olodi lọ,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ní Jóṣúà àti àwọn ọmọ ogun pa wọ́n ní ìpakúpa wọ́n sì pa gbogbo ọmọ ogun àwọn ọba máràrùn run, àyàfi àwọn díẹ̀ tí wọ́n tiraka láti dé ìlú olódi wọn.