Joshua 10:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
gbogbo àwọn eniyan pada sọ́dọ̀ Joṣua ní àgọ́ tí ó wà ní Makeda láìsí ewu. Kò sì sí ẹni tí ó sọ ìsọkúsọ sí àwọn ọmọ Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo enia si pada si ibudó sọdọ Joṣua ni Makkeda li alafia: kò sí ẹni kan ti o yọ ahọn rẹ̀ si awọn ọmọ Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn ọmọ ogun sì padà sí ọ̀dọ̀ Jóṣúà ní ibùdó ogun ní Mákédà ní àlàáfíà, kò sí àwọn tí ó dábàá láti tún kọlu Ísírẹ́lì.