Joshua 10:32 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA fi ìlú Lakiṣi lé àwọn ọmọ Israẹli lọ́wọ́, wọ́n sì gbà á ní ọjọ́ keji. Wọ́n fi idà pa gbogbo wọn patapata bí wọ́n ti ṣe pa àwọn ará Libina.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si fi Lakiṣi lé Israeli lọwọ, o si kó o ni ijọ́ keji, o si fi oju idà kọlù u, ati gbogbo ọkàn ti o wà ninu rẹ̀, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ṣe si Libna.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sì fi Lákísì lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́, Jóṣúà sì gbà á ní ọjọ́ kéjì. Ìlú náà àti gbogbo ènìyàn ibẹ̀ ní ó fi idà pá gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí Líbínà.