Joshua 10:39 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n gba ìlú náà, wọ́n mú ọba ibẹ̀. Wọ́n gba àwọn ìlú kéékèèké agbègbè rẹ̀ pẹlu. Wọ́n fi idà pa ọba wọn ati gbogbo àwọn ará ìlú náà. Gbogbo wọn ni wọ́n pa láìku ẹnìkan. Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe sí Heburoni, ati Libina ati ọba rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ṣe sí Debiri ati ọba rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si kó o, ati ọba rẹ̀, ati gbogbo ilu rẹ̀; nwọn si fi oju idà kọlù wọn; nwọn si pa gbogbo ọkàn ti mbẹ ninu rẹ̀ run patapata; kò si kù ẹnikan silẹ: gẹgẹ bi o ti ṣe si Hebroni, bẹ̃li o ṣe si Debiri, ati ọba rẹ̀; ati gẹgẹ bi o ti ṣe si Libna, ati ọba rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n gba ìlú náà, ọba rẹ̀ àti gbogbo ìlú wọn, wọ́n sì fi idà pa wọ́n. Gbogbo ènìyàn inú rẹ̀ ni wọ́n parun pátapáta. Wọn kò sì dá ẹnìkankan sí. Wọ́n ṣe sí Débírì àti ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wọn ti ṣe sí Líbínà àti ọba rẹ̀ àti sí Hébúrónì.