Joshua 10:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ará Gibeoni bá ranṣẹ sí Joṣua ní àgọ́ tí ó wà ní Giligali. Wọ́n ní, “Ẹ má fi àwa iranṣẹ yín sílẹ̀! Ẹ tètè yára wá gbà wá kalẹ̀, ẹ wá ràn wá lọ́wọ́. Nítorí pé, gbogbo àwọn ọba Amori, tí wọn ń gbé agbègbè olókè, ti kó ara wọn jọ sí wa.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọkunrin Gibeoni si ranṣẹ si Joṣua ni ibudó ni Gilgali, wipe, Má ṣe fà ọwọ́ rẹ sẹhin kuro lọdọ awọn iranṣẹ rẹ; gòke tọ̀ wa wá kánkán, ki o si gbà wa, ki o si ràn wa lọwọ: nitoriti gbogbo awọn ọba Amori ti ngbé ori òke kójọ pọ̀ si wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ará Gíbíónì sì ránṣẹ́ sí Jóṣúà ní ibùdó ní Gílígálì pé: “Ẹ má ṣe fi ìránṣẹ́ yín silẹ̀. Ẹ gòkè tọ̀ wà wá ní kánkán kí ẹ sì gbà wá là. Ẹ ràn wá lọ́wọ́, nítorí gbogbo àwọn ọba Ámórì tí ń gbé ní orílẹ̀ èdè òkè dojú ìjà kọ wá.”