Joshua 11:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Láti òkè Halaki títí lọ sí Seiri, títí dé Baaligadi ní àfonífojì Lẹbanoni ní ìsàlẹ̀ òkè Herimoni. Ó mú gbogbo àwọn ọba wọn, ó pa wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lati òke Halaki lọ, ti o lọ soke Seiri, ani dé Baali-gadi ni afonifoji Lebanoni nisalẹ òke Hermoni: ati gbogbo awọn ọba wọn li o kó, o si kọlù wọn, o si pa wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
láti òkè Hálakì títí dé òkè Séírì, sí Báálì-Gádì ní Àfonífojì Lẹ́bánónì ní ìsàlẹ̀ òkè Hámónì. Ó sì mú gbogbo ọba wọn, ó sì kọlù wọ́n, ó sì pa wọ́n.