Joshua 11:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí pé, OLUWA fúnra rẹ̀ ni ó mú kí ọkàn wọn le, kí wọ́n sì gbógun ti Israẹli, kí àwọn ọmọ Israẹli lè pa wọ́n run, kí wọ́n má baà ṣàánú wọn, ṣugbọn kí wọ́n pa wọ́n run gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori lati ọdọ OLUWA li a ti mu ọkàn wọn le, ki nwọn ki o le jade ogun tọ̀ Israeli wá, ki o le pa wọn run patapata, ki nwọn ki o má si ṣe ri ojurere, ṣugbọn ki o le pa wọn run, gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí OLÚWA fúnrà rẹ̀ ní ó sé ọkàn wọn le, kí wọn kí ó lè bá Ísírẹ́lì jagun, kí òun lè pa wọ́n run pátapáta, kí wọn má sì ṣe rí ojúrere, ṣùgbọ́n kí ó lè pa wọ́n, gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pàṣẹ fún Mósè.