Joshua 11:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní àkókò yìí ni Joṣua pa ìran àwọn Anakimu run patapata ní gbogbo àwọn ìlú tí ó wà lórí òkè, àwọn ìlú bíi: Heburoni, Debiri, Anabu, ati àwọn ìlú tí wọ́n wà lórí òkè Juda, ati àwọn ìlú tí wọ́n wà lórí òkè Israẹli, gbogbo wọn patapata ni Joṣua parun, ati gbogbo ìlú wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li akokò na ni Joṣua wá, ti o si ke awọn ọmọ Anaki kuro ni ilẹ òke, kuro ni Hebroni, kuro ni Debiri, kuro ni Anabu, ati kuro ni gbogbo ilẹ òke Juda, ati kuro ni gbogbo ilẹ òke Israeli: Joṣua run wọn patapata pẹlu ilu wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní àkókò náà ni Jóṣúà lọ tí ó sì run àwọn ará Ánákì kúrò ní ilẹ̀ òkè, láti Hébúrónì, Débírì, àti ní Ánábù, àti gbogbo ilẹ̀ Júdà, àti kúrò ní gbogbo ilẹ̀ òkè Ísírẹ́lì. Jóṣúà sì run gbogbo wọn pátapáta àti ìlú wọn.