Joshua 12:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun àwọn ọba wọnyi, wọ́n sì gba gbogbo ilẹ̀ wọn tí ó wà ní apá ìlà oòrùn, ní òdìkejì odò Jọdani, láti àfonífojì Arinoni títí dé òkè Herimoni, pẹlu gbogbo agbègbè Araba ní apá ìlà oòrùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
NJẸ wọnyi ni awọn ọba ilẹ na, ti awọn ọmọ Israeli pa, ti nwọn si gbà ilẹ wọn li apa keji Jordani, ni ìha ìla-õrùn, lati odò Arnoni lọ titi dé òke Hermoni, ati gbogbo pẹtẹlẹ̀ ni ìha ìla-õrun:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí àwọn ará Ísírẹ́lì ṣẹ́gun, tí wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn ní ìlà-oòrùn Jọ́dánì, láti Ánónì-Gọ́gi dé Okè Hámónì, pẹ̀lú gbogbo ìhà ìlà-oòrùn aginjù: