Joshua 12:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun àwọn ọba wọnyi, ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Jọdani, wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn, láti Baaligadi ní àfonífojì Lẹbanoni títí dé òkè Halaki, ní apá Seiri. Joṣua pín ilẹ̀ wọn fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wọnyi li awọn ọba ilẹ na, ti Joṣua ati awọn ọmọ Israeli pa li apa ihin Jordani, ni ìwọ-õrùn, lati Baali-gadi li afonifoji Lebanoni ani titidé òke Halaki, li ọ̀na òke Seiri; ti Joṣua fi fun awọn ẹ̀ya Israeli ni ilẹ-iní gẹgẹ bi ipín wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí Jóṣúà àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sẹ́gun ní ìhà ìwọ̀-oòrùn Jọ́dánì, láti Báálì Gádì ní Àfonífojì Lẹ́bánónì sí Okè Hálákì, èyí tí O lọ sí ọ̀nà Sérì (Jóṣúà sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì ní ilẹ̀ ìní gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà wọn: