Joshua 12:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ninu ilẹ̀ náà ni àwọn ìlú tí wọ́n wà lórí òkè wà, ati àwọn tí wọ́n wà ní ẹsẹ̀ òkè, ati àwọn tí wọ́n wà ní Araba, ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè, ní aṣálẹ̀, ati ní Nẹgẹbu. Àwọn tí wọ́n ni ilẹ̀ yìí tẹ́lẹ̀ rí ni àwọn ará Hiti ati àwọn ará Amori, àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi, ati àwọn ará Jebusi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ni ilẹ òke, ati ni ilẹ titẹju, ati ni pẹtẹlẹ̀, ati li ẹsẹ̀-òke, ati li aginjù, ati ni Gusù; awọn Hitti, awọn Amori, ati awọn ara Kenaani, awọn Perissi, awọn Hifi, ati awọn Jebusi:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
ilẹ̀ òkè, ní ẹsẹ̀ òkè ní ìhà ìwọ̀-oòrùn òkè aginjù, ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè, ní asálẹ̀ àti Négéfi ilẹ̀ àwọn ará: Hítì, Ámórì, Kénánì, Pérísì, Hífì àti àwọn ará Jébúsì):