Joshua 13:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
gbogbo ilẹ̀ ọba Ogu ti Baṣani, tí ó jọba ní Aṣitarotu ati Edirei. Ogu yìí nìkan ṣoṣo ni ó ṣẹ́kù ninu ìran Refaimu yòókù. Mose ti ṣẹgun gbogbo wọn, ó sì ti lé wọn jáde.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo ilẹ ọba Ogu ni Baṣani, ti o jọba ni Aṣtarotu ati ni Edrei, ẹniti o kù ninu awọn Refaimu iyokù: nitori awọn wọnyi ni Mose kọlù, ti o si lé jade.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìyẹn, gbogbo ilẹ̀ ọba Ógù ní Básánì, tí ó jọba ní Áṣítarótù àti Édérì, ẹni tí ó kù nínú àwọn Réfáítì ìyókù. Mósè ti ṣẹ́gun wọn, ó sì ti gba ilẹ̀ wọn.